Numeri 1:4-16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.
5 “Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:
“Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri;
6 Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai;
7 Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu;
8 Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Ṣuari;
9 Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni;
10 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu:
láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu;
Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri;
11 Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni;
12 Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai;
13 Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri;
14 Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli;
15 Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”
16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.